Ilu Ibadan min titi lọjọ ti Olumọ atawọn eeyan ẹ darapọ mọ OPC New-Era - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday 8 November 2023

Ilu Ibadan min titi lọjọ ti Olumọ atawọn eeyan ẹ darapọ mọ OPC New-Era


 Ọrọ naa ti ja nilẹ tipẹ pe wahala bẹ silẹ laarin ẹgbẹ OPC ti Gani Adams nipinlẹ Ọyọ, eyi to mu ki alakooso ẹgbẹ naa atawọn ọmọ ẹyin ẹ fi ọdọ Aarẹ ọna Kankafo yii silẹ lọ darapọ New Era tawọn naa jẹ ọmọ ẹgbẹ Oodua bakan naa.

Lọsẹ to kọja lọ, iyẹn ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ni aṣiiri ọrọ naa tu sita nigba ti alakooso ẹgbẹ naa, Rotimi Oguntunde Olumọ, bọ sita gbangba lati sọ faraye pe awọn ti kuro lẹyin ọga wọn tẹlẹ yii, Iyẹn Aarẹ Gani Adams, tawọn si ti wa lẹyin Oloye Rasak Arogundade Balogun, to jẹ aarẹ ti New Era.

Ninu iwadii wa ta a gbọ to mu ki ipinlya ọhun waye ko ṣe lẹyin ẹsun ti wọn ni Gani Adams fi kan Olumọ, to jẹ alakoso ẹgbẹ ẹ nipinlẹ Ọyọ tẹlẹ pe o lọọ gba owo lọwọ Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu lakooko ibo aarẹ to waye lorieede yii ninu ọdun yii.

Wọn sọ pe ọrọ naa di iṣu ata yanyan ninu ẹgbẹ ọhun to mu ki Aarẹ ọna Kankafo ni ki alakoso ọhun lọọ rọkun nile fun igba diẹ. Gbogbo awijare Olumọ nigba naa lọhun pe oun kọ mọ nipa ẹsun ti wọn fi kan oun ati pe oun ko ri ẹni ti wọn pe ni Tinubu lojukoju ri, kọ wọ ọga ẹ leti.

Ṣugbọn nigba ti wọn ni wọn ṣewadii ti wọn ko ri ootọ ọrọ di mu nibẹ, ti wọn ni ọga wọn yii si kọ lati tọrọ aforiji fun ẹsun ibanilorukọ jẹ yii ni Olumọ atawọn eeyan ẹ yii ṣe pinnu ti wọn si fẹgbẹ naa silẹ darapọ mọ New-Era.

Lọjọ Iṣẹgun, to kọja yii ni gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ New Era yii pe si Mapo niluu Ibadan, nibi ti wọn ti ṣefilọlẹ awọn oloye tuntun ẹgbẹ naa, ti Olumọ ṣi pada sipo alakoso ẹ.Bẹẹ naa ni wọn tun lo anfaani yii lati fi ṣe ipade ẹgbẹ lapapọ, ti wọn maa n ṣe. Igba akọkọ si ree, ti wọn yoo gbe iru ipade bẹẹ kuro ni Eko.

 Ninu ọrọ Oloye Rasak Arogundade, tọpọ tun mọ si Saddam, lo ti ki awọn ọmọ ẹgbẹ tuntun naa kaabọ, lo ti  lo akoko ọhun lati kan si Aarẹ Bọla Tinubu, fun ipo to wa yii, eyi to ni Oloye Ọbafẹmi Awolọwọ ati Oloye Moshood Abiọla tiraka lati de,amọ ti Olodumare ko gba fun wọn.

O ni ko waa lo akoko ọrọ kan to n sọ nigba ipolongo ibo ẹ pe ‘’Emi lo kan’’ lati koju ipenija to n koju awọn ọmọ orileede yii.O ni ko fi ọna ti atunṣe yoo fi deba ọrọ aje tawọn araalu ko fi ni kabamọ pe awọn fi ibo wọn gbe e wọle.

Bakan naa lo tun ran awọn ọmọ Yoruba leti lati ma ṣe jẹ ki ogun to waye lakooko Usman Dan-Fodio, tun waye niluu Ilọrin, nitori  o ni gbogbo nnkan to waye bayii nibẹ ki i ṣe ọrọ ẹsin rara, wọn kan fẹẹ lo awọn ọmọ Yoruba to wa nibẹ, lati fi da wahala silẹ.

Bẹẹ lo rọ awọn oloye ẹgbẹ tuntun nipinlẹ Ọyọ lati waa ni isọkan, ki wọn si jẹ ọrọ ọmọ Oodua jẹ wọn lọkan.  Ko to akoko yii ni Oloye Adeagbo Adeọla Musediq, to jẹ igbakeji aarẹ ẹgbẹ ọhun, ti  sọ fun oniroyin wa pe inu oun dun fun ayẹyẹ ti wọn ṣe lọjọ naa.

Gẹgẹ bo ṣe wi, o ni oun loun wa nipo ti alakooso fẹgbẹ OPC nipinlẹ Ọyọ labẹ Gani Adams tẹlẹ ṣugbọn awọn iwa to n hu yii, bo tilẹ jẹ pe ko darukọ, nipa ọrọ olowo de lo mu u kawọn fẹgbẹ ọhun fi silẹ, nitori awọn mọ pe ki i ṣe adari rere.

Idi niyii to fi ni ki Olumọ to jẹ igbakeji oun gba ipo naa, amọ oun waa dupẹ pe gbogbo ọrọ tawọn sọ nipa ẹ lo wa ja si ootọ bayii. O waa sọ pari ọrọ ẹ pe,’’ Mo ti maa n sọ nigba gbogbo pe ko mọ nipa ipo adari, ẹyin naa , ẹ tun gbọ nnkan to ṣẹlẹ sii laipẹ ti iyawo atawọn fi i silẹ, sa lọ siluu oyinbo, ṣe ẹni ti ko ba le dari ile ẹ, ṣe o le dari ilu’’

Lara awọn to wa nibẹ lọjọ naa ni Ọba Eddy Oyewọle, Onifọkọ tiluu Fọkọ,Iyalọja gbogbogboo niluu Ibadan atawọn eeyan pataki mi-in. Awọn oloye tuntun ti wọn ṣebura fun un ni  Rotimi Olumọ, Alakooso OPC ni Ọyọ,Wasiu Azeez, igbakeji ẹ,Taju Ogunrẹmi, oluṣiro owo, Saliu Olodo ni akapo wọn, nigba ti Ade Adeniji jẹ alukori ẹgbẹ atawọn yooku.

               

No comments:

Post a Comment

Pages