Awọn aṣobode ri apo irẹsi ti wọn ko ọta ibọn pamọ si nipinlẹ Ogun . - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday 29 November 2023

Awọn aṣobode ri apo irẹsi ti wọn ko ọta ibọn pamọ si nipinlẹ Ogun .


 .   Ọga agba fun ẹṣọ aṣobode nipinlẹ Ogun, Ahmadu
  Shuaib, ti ṣafihan ọta ibọn to fẹẹ to ẹgbẹrun kan, iyẹn 975 , ti  wọn ko pamọ sinu apo irẹsi lẹyin ti wọn
ta wọn lolobo pe awọn kan fẹẹ ko wọlu lati Imẹkọ
 Afọn.

Lakooko to n ṣafihan ọhun lọjọruu, Wẹsidee fawọn
 oniroyin, ni Idi-Iroko, o sọ pe inu apo irẹsi marun-un ni wọn tọju awọn ọta ibọn naa si.

Ọga aṣobode tun fikun ọrọ ẹ pe iṣẹ  si  n lọ  labẹlẹ      lati mọ awọn oniṣẹ ibi naa atawọn to ran wọn. O sọ pe  aṣeyọri nla lo jẹ fun ileeṣẹ naa.O sọ pe, "Pẹlu idunnu ni mo fi sọ fun yin lonii nipa
aṣeyọri nla ta a ṣe  lonii nipa erongba awọn ọta lati
ko ọta ibọn wọlu.Bi ẹ ṣe ri wa lonii jẹ ki ẹ mọ nipa
ifarajin wa fun eto aabo fawọn araalu.

 Shuaibu tun fikun ọrọ ẹ pe ṣiṣe fayawọ awọn nnkan
ija ogun jẹ eyi to buru ju, ti ko si yẹ ka foju bintin wo lawujọ, nitori ẹ lawọn ko ṣe faaye silẹ,kawọn
ẹni ibi lo anfaani lati ko o wọlu.O ni lara idi tawọn ko fi gbọdọ foju awọn fayawọ balẹ ni pe awọn  nnkan ija oloro yii ni wọn fi n ro awọn ọdaran lagbara lati maa ṣiṣẹ ibi. Nitori ẹ lawọn ko fi  ni maa wo wọn niran lati ba ilu jẹ .    

Ọga naa tun tan imọlẹ si ọrọ ẹ pe lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu yii ni wọn rawọn ọta ibọn
naa nibi ti wọn ko wọn pamọ si ni inu igbo to
 wa  lọna aafin ọba Ayeroro.Bẹẹ lo gboriyin fawọn ọmọọṣẹ ẹ fun iṣẹ akọni ti  wọn ṣe pẹlu idaniloju pe aabo to peye yoo wa fun gbogbo ọmọ  orileede yii .


No comments:

Post a Comment

Pages