Yanko Aliya fẹẹ dalubolẹ fawọn oloolufẹ ni Ibafo - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 13 October 2023

Yanko Aliya fẹẹ dalubolẹ fawọn oloolufẹ ni Ibafo


 

Gbogbo eto lo ti pari bayii fun gbajumọ olorin fuji obinrin nni, Yanko Aliya, fun ere alarinrin to fẹẹ fi da awọn oloolufẹ ẹ lara ya lọjọ Ẹti, Furaidee, ti ṣe ọjọ Kẹwaa, oṣu kọkanla ọdun yii.

Ootẹli Dap Mud to wa ni Ibafo,  nipinlẹ Ogun, ni ere ọhun yoo ti waye, nibi ti yoo ti dalubolẹ fawọn oloolufẹ ti wọn n bọ lọjọ naa.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, alẹ ọjọ naa yoo larinrin nitori awọn eeyan jakankan ni yoo wa nibi ere ọhun.

Aṣiwaju Ibafo ti wa ke si gbogbo awọn eeyan lati waa yẹ Yanko Aliya si lalẹ ọjọ naa pẹlu idaniloju pe ko nii doju ti wọn.

Bakan naa ni Yanko Aliya naa ti sọ pe kawọn oloolufẹ ẹ ma bẹru pe wọn ko nii fi akoko wọn ṣofo lalẹ ọjọ naa, nitori awọn orin alaadun toun yoo fi da wọn lara ya.

O ni gẹgẹ bi wọn ṣe mọ oun tẹlẹ pe oun ko figba akn doju ti wọn ri bẹẹ naa ni yoo ri ni ọjọ kẹwaa, oṣu to n bọ yii, eyi to bọ si ọjọ Ẹti, Furaidee.  


No comments:

Post a Comment

Pages