Wọn ti bẹrẹ ayẹyẹ ọdun ọmọ Olowu - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday, 26 October 2023

Wọn ti bẹrẹ ayẹyẹ ọdun ọmọ Olowu


 

Jamiu Ademoye

Lọjọ Aje, ọsẹ yii ni wọn bẹrẹ ayajọ ọdun ọmọ Olowu, eyi ti wọn maa n ṣe lọdọọdun, nibi ti gbogbo awọn ọmọ Olowu jakejado  agbaaye yoo ti peju pesẹ, eyi ti wọn sọ pe o waa fun isọkan, imuyangan , agbega ati ajọṣepọ to danmọran.

 

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, fun odidi ọsẹ kan ni wọn sọ pe eto ọhun yoo fi waye,lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu yii ni wọn yoo pari ẹ. Gẹgẹ bi Ọba Saka Adelọla Matẹmilọla, Olowu tilu Owu, ṣe wi lara awọn eti ti wọn la silẹ ni adura lati ọdọ awọn adari ẹlẹsin mẹtẹẹta. Eyi ti wọn ti ṣe, bẹẹ naa ni wọn tun ti ṣe ayẹwo ilera.

 

Ọjọbọ, Tọsidee, onii, ni ipatẹ  awọn ohun iṣẹnbaye, afihan ati igbelaruge aṣa yoo waye, eyi ti wọn sọ pe yoo kun fun ọpọ iṣe ọna, Òwò fun idagbasoke ati ilọsiwaju. Bẹẹ naa ni iyawo Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ yoo tun da wọn lẹkọọ pẹlu.

 

Ọla ọjọ Ẹti, Furaidee, ni wọn yoo fawọn kan joye lara awọn oye ti wọn ypp fi jẹ ni Aarẹ Alasa, Aarẹ Ajagunla, ati Obagbọ pẹlu Yeye Obagbọ  tilu Owu.

 

Ojo Abamẹta, Satide, ni aṣekagba ayẹyẹ naa nigba ti gbogbo ọmọ Owu yoo ti pejọ  jọ ṣayẹyẹ ọhun. Gbogbo ilu ati igberiko ni yoo wa pelu awọn aṣoju wọn lati ṣafihan aṣa oriṣi.

 

No comments:

Post a Comment

Pages