Bi gbogbo nnkan ba n lo, bo se n loo yii, ojo Isegun, Tusidee, ojo kokanlelogbon yoo min titi, nigba ti tawon omo egbe Oodua People Congress, OPC New- Era, ba n da ariya repete sile ti yoo waye ni Mapo niluu Ibadan.
Gege ni bi atejade ti Aare egbe naa Oloye
Rasak Arogundade Balogun, fowo si ti Alexandra Adesina fi sita. O salaye pe ojo naa ni won yoo sefilole awon oloye tuntun ti eka ipinle Oyo bee naa ni ipade gbogbogboo OPC New Era yoo tun waye.
Lara awon ti won n reti lojo naa ni Gomina ipinle Oyo, Seyi Makinde, ti yoo je alejo pataki, Oba Mahood Ali Balogun,Olubadan tiluu Ibadan ni baba ojo naa.
Awon yooku tun ni Onarebu Wasiu Olatunbosun,komisanna fun asa ati irinajo afe nipinle Oyo, ni olufilole pataki,Komureedi Rotimi Oguntunde Olumo,alakoso egbe naa nipinle Oyo, oun ni olugbalejo nigba ti Oloye Aladesewa naa je lara olugbalejo. Aare egbe naa, Arogundade Balogun atawon oloye egbe lapapo yoo wa nikale lojo naa.
New era moving train move on Ibadan yaaa
ReplyDeleteIn Sadam, OPC New Era, We all Stand.
ReplyDelete