Obìnrin Onílù Àrà, Àràlọlá di gómìnà ẹgbẹ́ PMAN l’Ékòó - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 23 September 2023

Obìnrin Onílù Àrà, Àràlọlá di gómìnà ẹgbẹ́ PMAN l’Ékòó
Wọn ti yan gbajugbaja obinrin to n filu dara, Arabinrin Sẹrifatu Ọlamuyiwa ti gbogbo aye mọ si Ara gẹgẹ bi  gomina ẹgbẹ awọn olorin iyẹn PMAN, nipinlẹ Eko.

Ọsẹ to kọja yii ni aarẹ ẹgbẹ naa, Pretty Okafor fọwọ si yiyan sipo obinrin ọlọpọlọ pipe yii gẹgẹ bi aṣaaju awọn olorin nipinlẹ Eko.

Pẹlu ipo ti wọn yan an si yii,  Ara ni yoo maa tukọ ẹgbẹ yii nipinlẹ Eko titi digba ti wọn yoo fi dibo yan awọn oloye tuntun.

A gbọ pe nitori ipa ribiribi ti ọmọ bibi ilu Ondo naa ti ko fun idagbasoke ati ilọsiwaju ariya lorileede yii ni wọn ṣe yan an sipo naa.

Lasiko to n ba wa sọrọ, Ara ni inu mi dun, ayọ mi kun fun ipo ti wọn yan mi si yii, mo mọ pe igbagbọ ti ẹgbẹ ni si mi lo jẹ ki wọn yan mi sipo yii, mo si ṣetan lati lo gbogbo imọ ati iriri mi lati gbe ẹgbẹ yii ga ju bo ṣe wa lọ.

No comments:

Post a Comment

Pages