Tinubu gbodo fiya je Dapo Abiodun lori iwa to hu sawon alaga ijoba ibile- Segun Sowumi - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday 31 August 2023

Tinubu gbodo fiya je Dapo Abiodun lori iwa to hu sawon alaga ijoba ibile- Segun SowumiOtunba Segun Sowumi, okan lara agba egbe oselu PDP, nipinle  Ogun ti ro Aare Bola Ahmed Tinubu lati da seria to ba to fun Gomina Dapo Abiodun lori iwa gaaba to n je lori awon alaga kansu.

Ninu atejade ti okunrin naa fi sita lori fonran kan ti won fi sita nibi tawon alaga kansu ti n dobale fun Gomina, o so pe ko si nnkan to buru nibe, nitori gege bi asa Ile Yoruba.

Sugbon o tun so pe o buru nitori aimokan to n da Omooba Dapo Abiodun laamu pe ipin meta nijoba pin si.

Ati pe ijoba ibile ko se e fowo ro seyin gege bi leta to ni Wale Adedayo ko sita lori awon owo to je ti kansu.

Sowumi tun salaye pe itiju nla gba a ni bi won se pin fonran fidio idobale naa sita, pelu ibeere pe ta lo gba ijoba lamoran lati ya fidio naa tabi fon sita. O ni nigba ti won mo on mo yeye awon alaga ijoba ibile naa ni.

O waa ro Aare orileede wa lati se iwadii finnifinni lori isele naa, Ko si lo ofiisi e yii lati se nnkan to to. Bee lo tun ran an lati pe Gomina Dapo Abiodun yii kan naa lo ran awon toogi si oun laipe yii.

O ni ti Gomina ba le se iru nnkan bee fawọn alaga ijoba ibile, ko buru ju bi Aare ba le da seria fun un pe ko maa fo bi opolo.


No comments:

Post a Comment

Pages