Ọsẹ to n bọ ni ayẹyẹ ọdun Aje Olokun OPC New Era - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 18 August 2023

Ọsẹ to n bọ ni ayẹyẹ ọdun Aje Olokun OPC New Era



 

Gbogbo eto lo ti pari fun ayẹyẹ ọdun Aje Olokun ti ẹgbẹ Oodua Peoples Congress, OPC New Era, maa n ṣe lọdọọdun. Gẹgẹ bi Oloye Oyename to jẹ akọwe gbogbogboo ẹgbẹ ọhun ṣe wi, lorukọ Oloye Rasak Arogundade Balogun,aarẹ wọn.

 

Ọtunla, Monde, ọjọ Aje, ọjọ kọkanlelogun si ọjọ Iṣẹgun, ọjo kejilelogun, oṣu yii,  ni  yoo waye ni Debojo Beach, Ẹlẹkọ, Ibeju Lekki, nipinlẹ Eko.

 

Lati aarọ, ọjọ Aje, Monde, ọjọ kọkanlelogun, lawọn ọmọ naa yoo ti maa de si ibudo naa, fawọn etutu ti wọn kọkọ maa n ṣe mọjumọ ọjọ keji, ọjọ naa gan-an ni wọn ti kọkọ maa n bọ aje olokun yii.

 

Nigba ti aṣekagba yoo waye lọjọ Isẹgun, nigba ti  wọn yoo lọọ ṣadura ni eti okun, ti ayẹyẹ iwẹjẹ-wẹmu yoo si bẹrẹ,ọba orin nni,Saheed Oṣupa yoo ni yoo ṣere fun wọn lọjọ naa.

 

Lara awọn ti wọn n reti nibẹ ni Ọba Saliu Babatunde Saliu,Oloworo tiluu Oworo, ti yoo jẹ Baba ọba Alade lọjọ naa, nigba ti Ọba Ajibọla Talabi Odugbẹsan,Onidebojo tiluu Debojo jẹ olugbalejo pataki.

 

Awọn yooku tun ni Oloye Ifagbemi Oṣungbemi Omitunmise, to jẹ Iya ooṣa Ipakoda Ikorodu ni mama ọjọ naa nigba ti Oloye Olabọsipo Ọlasẹinde,Iyalaje oodua gbogbogboo naa ko ni gbẹyin


No comments:

Post a Comment

Pages