Awọn Fulani lo fẹẹ tun dọgbọn da ogun silẹ ni Ilọrin- Aarẹ OPC, New Era - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 26 August 2023

Awọn Fulani lo fẹẹ tun dọgbọn da ogun silẹ ni Ilọrin- Aarẹ OPC, New Era



Aarẹ fẹgbẹ Oodua Peoples Congerss, New Era, Oloye Rasak Arogundade Balogun ti kilọ fawọn to fẹẹ da wahala silẹ nipinlẹ Kwara, paapaa julọ niluu Ilọrin, lati gbakiyesi ara ati pe nnkan to n ṣẹlẹ lọhun kọja,musulumi atawọn oni iṣẹṣe, o ni wọn fẹẹ ki iru ogun to waye nigba aye Dan fodio, tun wa ṣẹlẹ ni.

Ọkunrin naa sọrọ yii nibi ayẹyẹ ọdun Aje Olokun, to waye lọjọ Aje ati Iṣẹgun, to kọja yii ni Debọjọ, Ẹlẹkọ, niluu Ibẹju-Lekki, nipinlẹ Eko. O sọ pe erongba awọn Fulani nigba naa ni lati gba gbogbo ilẹ Yoruba pata bẹrẹ lati ilu Ilọrin.

O ni ko to waa di pe wọn bori wọn ni Oṣogbo, nigba ti wọn ko ju wọn lọdun !812, o ni ija  naa si ree, aṣẹ ti Usman Dan Fodio, fun awọn Alimi ni pe ki wọn rii pe wọn gba ilẹ Yoruba ki wọn di iran Fulani. O ni nigba ti ko si aye lati maa jagun mọ, lo di pe ọrọ oṣelu lo pada si.

Ọkunrin naa tun sọ pe,’’ Ẹ o ri pe ko si ninu ijọba taa ni lorileede yii, ti Fulani ko fẹẹ maa gba gbogbo ẹ.Wọn wa ṣe debi ẹni pe ipinlẹ to wa ni ṣakani ọdọ wọn jẹ mọkandinlogun, nilẹ Yoruba jẹ mẹfa awọn Ibo naa mẹfa. Ṣe ẹ waa rii pe ko si bi ẹ ṣe fẹẹ ba wọn ja, ti ẹ le bori wọn’’

O ni ọpọ awọn aṣaaju wa ni ko mọ nnkan ti wọn n ṣe, nitori ni idile wọn, wọn n ṣe oriṣa nibẹ. O ni Fulani ko ba wa faa pe ka fi ilu silẹ fun wọn, o ni wọn fẹẹ mu wa lẹru ni. O ni ko dara bi wọn ṣe waa n lo awọn aafaa lati ma ti tako awọn.O ni ko wa yẹ ki wọn gba fun wọn lati lo wọn tako ọmọọya wọn nilẹ Yoruba.

Bakan naa lo tun sọ ninu ọrọ apilẹkọ ẹ lọjọ naa ipa ti Aje Olokun n ko gẹgẹ bi oriṣa nilẹ Yoruba ati idi Pataki ti ẹgbẹ OPC New Era, fi gba lati wa maa bọ lọdọọdun ni okun to wa Dabọjọ, Ẹlẹkọ,Ibẹju Lekki.

 

Arogundade tun ṣalaye siwaju pe lọdun to kọja oun ranti pe nigb to yoo ba fi di ọdun yii awọn nnkan rere yoo maa ṣẹlẹ ninu igbesi aye awọn ọmọ ẹgbẹ atawọn araalu Debọjọ, oun si dupẹ pe Olodumare muu ṣẹ.

 

O ni ọkan lara ẹ ni to tun jẹ ẹri rere ni Baalẹ ilu naa, ti wọn fun ni igbega sipo Ọba alaye bayii, aṣeyọri nla lo pe fun Aje Olokun.

O waa sọ pe bi wọn ṣe n sọdun naa oun ko ni saisọ ẹdun ọkan oun lori ọwọ tawọn kan fi mu iṣẹṣe, O ni oṣu kẹjọ la waa yii, o ṣoro fawọn kan lati fi oṣu ọhun polongo ati agbega iṣẹṣe, ti ko yẹ ko ri bẹẹ.

O ni ẹdun ọkan lo jẹ lori iha ti Oluwo tiluu Iwo fi mu ọrọ iṣẹṣe, ko si yẹ ko ri bẹẹ nitori ipo to wa, amọ itiju nla lo jẹ fun iran ilẹ Yoruba. Bakan naa lo tun fi aidunnu ẹ han lori bawọn kan ṣe doju ija kọ awọn to lọọ bọ Ọṣun Oṣogbo lakooko ọdun wọn to waye laipẹ yii.

Lara awọn nnkan to waye nibi ayẹyẹ ọdun Aje Olokun tọdun yii naa ni ṣiṣe etutu fun Aje gẹgẹ bi wọn ṣe maa n ṣe lọdọọdun ati ayẹyẹ aṣekagba, nibi ti wọn ti fun Aarẹ ẹgbẹ naa ni ẹbun Aje. Bẹẹ ni awọn kan tun gba ami ẹyẹ lọjọ naa,

Paripari ẹ ni ti Saheed Oṣupa to fere da wọn lara ya lọjọ naa. Gbogbo ọmọ ẹgbẹ OPC New Era kaakiri orileede yii lo peju sibẹ lọjọ naa.

 

No comments:

Post a Comment

Pages