Awọn eeyan Adunbu, ni Itori, nijọba ibilẹ Ewekoro, nipinlẹ Ogun, tun ti rọ Gomina Dapọ Abiọdun, tipinlẹ ọhun, lati ma ṣe wo awọn niran lori bawọn ajagungbalẹ ṣe fẹẹ abule wọn mọ wọn lọwọ, ti wọn si n fojoojumọ mu ifoya bawọn.
Ninu iwọde ti wọn ṣe laipẹ yii lawọn eeyan naa ti fi aiduunu wọn lori bi wọn ṣe ni awọn ajagungbalẹ ti wọn ni Baba Owoẹyẹ, jẹ aṣaaju wọn, ṣe n ya wọ abule ọhun ti wọn si n lu awọn ara abule ọhun, ti wọn tun ba nnkan ini wọn jẹ.
Ninu ọrọ ti Baalẹ ilu naa, Kayọde Falọla, ba oniroyin wa sọ nigba taa ṣabẹwo sọdọ ẹ, nibi to ti n gba itọju ni ọsibitu, o sọ pe ọjọ manigbagbe lọjọ tawọn ajagungbalẹ ọhun ti wọn to ọgbọn wa ka oun mọle, ti wọn lu oun, ba ile oun jẹ bẹẹ ni wọn tun de oun ni okun bi ẹni de ẹran mọlẹ.
O sọ pe ọkunrin kan ti wọn pe ni Mojeed Ẹnitiwa, to wa lọgbọn ẹwọn ni awọn ẹyin ẹ wa lọjọ naa, ti wọn si pariwo pe awọn ko waa ba a ṣere rara, awọn wa gba ẹmi oun ni, o ni Ọlọrun lo yọ oun lọjọ naa, gbogbo awọn to jade lati waa gba pun, lo ni wọn fi oko , igo ati ada lee pada.
O ni siyalẹnu oun, bi wọn ṣe de oun mọlẹ, ni ọkan lara wọn pe Mojeede lori foonu pe ọwọ awọn ti ba mi, awọn maa gbẹmi oun ni, o ni Ọlọrun lo yọ oun lọjọ oun ko ba ti dẹni agbegbin.
Nibi iwọde tawọn araalu ṣe lọjọ naa pẹlu oriṣiriṣi akọle ni wọn ti rẹ ijọba ipinlẹ Ogun, ijọba orileede yii ki wọn gba awọn o, nitori awọn ko le foju mẹrẹẹrin wọn sun mọ, nitori ipaya awọn ajagungbalẹ yii.
No comments:
Post a Comment