Tinubu gbọdọ tete gbe igbesẹ lori iṣoro tawọn ọmọ orileede yii koju- Ambasedọ Ajadi - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Monday 31 July 2023

Tinubu gbọdọ tete gbe igbesẹ lori iṣoro tawọn ọmọ orileede yii koju- Ambasedọ Ajadi



 

Ambasedọ Olufẹmi Ajadi Oguntoyinbo, oludije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu New Nigeria's People's Party, (NNPP)  nipinlẹ Ogun, ti rọ Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, lati tete gbe igbesẹ lori iṣoro tawọn ọmọ orileede yii koju lakooko yii, paapaa julọ lori yiyọ owo iranwọ epo pẹtiroolu iyẹn sọbsidi.

 

Ọkunrin naa sọrọ yii ninu atẹjade kan to fi sita lonii, ọjọ Aje, Monde,  o sọ pe nnkan le koko fawọn ọmọ orileede lakooko yii, idi si niyi ti Aarẹ fi le tete wa nnkan ṣeko to di pe o buru ju.

 

O sọ pe o yẹ ki Tinubu ti kọkọ ti gbimọ awọn nnkan imunudun ko to de pe o gbe aba yiyọ owo iranwọ epo tijọba maa n ṣe yii. O waa fi aidunnu ẹ han si bawọn ọmọ orileede yii ṣe n gbe ninu inira.

 

 

Oguntoyinbo tun ṣalaye pe lakọkọ naa, ko si nnkan to yẹ ko tun maa dena ẹbun iranwọ iyẹn paletifu ti wọn lawọn fẹẹ ṣe, nitori eto ijọba yii ti le ju fawọn ọmọ Naijiria.

 

 

O fikun ọrọ ẹ pe, " Akoko ti to fun Aarẹ wa lati ṣafikun owo oṣu awọn oṣiṣẹ ijọba, tt eleyii ba si ti waye, ki wọn maa gbagbe awọn oṣiṣẹ-fẹyinti. Gẹgẹ bi mo ṣe maa n sọ, ẹgbẹrun lọna igba naira ko kere ju fawọn oṣere to kere ju, latigba ti wọn ti yọ owo iranwọ epo’’

 

 

"Bi nnkan bayii ba waye tawọn oṣiṣẹ to kere ju n gba ẹgbẹrun lọna igba naira loṣu, o tumọ si pe Aarẹ wa jẹ ẹni to laanu, to imayedẹrun awọn eeyan ẹ si jẹ ẹ logun.’’

 

 

Lori awọn minisita ti Aarẹ yan, Ambasedọ awọn ọdọ, sọ pe awọn orukọ ti wọn gbe jade jẹ eyi to ba ni lọkan jẹ, to si doju ti ni, nitori pe erongba awọn ni pe wọn yoo yan awọn ọdọ

 

Oguntoyinbo fikun ọrọ ẹ pe, " Ohun ta a n reti tẹlẹ ni pe kawọn ọdọ ti wọn san leegun, ti wọn ni okun ati agbara wa ninu awọn ti Aarẹ yoo yan gẹgẹ bi minisita, ki i ṣe awọn agba ti wọn ti gbo nidii oṣelu’’

 

 

" Ohun to orileede wa n fẹ lakooko yii lawọn ọdọ bi ohun amuṣagbara, ki i ṣe awọn arugbo, ti wọn ko ni nnkan gigi ṣe fawọn eeyan wọn fun odidi ọdun mẹjọ. O ku diẹ kaato fun Aarẹ wa fun iru awọn to yan lati ba a ṣiṣẹ pọ, ọpọ wọn lo jẹ pe wọn ti wa ninu ijọba lati ọdun 19191. Ọdọ ti ọpọlọ ẹ ji pepe ni orileede yii n fẹ lakooko yii’’

 

No comments:

Post a Comment

Pages