Ṣẹ́gun Ṣówùnmí fẹjọ́ Dàpọ̀ Abíọ́dún sun ọ̀gá ọlọ́pàá pátápátá lórílèèdè yìí, lórí áwọn aṣekúpani - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 23 June 2023

Ṣẹ́gun Ṣówùnmí fẹjọ́ Dàpọ̀ Abíọ́dún sun ọ̀gá ọlọ́pàá pátápátá lórílèèdè yìí, lórí áwọn aṣekúpani



Bo tilẹ jẹ pe ko tii ju ọsẹ kan lọ ti Ọtunba Ṣẹgun Ṣowunmi kọ lẹta si Nuhu Ribadu, to jọ oludamọran pataki fun aarẹ lori eto abo lati gba wọn lọwọ Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun, lori bo ṣe sọ pe o n lo awọn janduku lati fi kọju ija si sawọn alatako nitori igbẹjọ to n lọ lọwọ.

 

Ni bayii, o tun ti kọ lẹta mii-in si adele ọga agba pata fawọn ọlọpaa, Kayọde Ẹgbẹtokun, lori ẹsun yii bakan naa ati bo ṣe ni bawọn tọọgi ṣe kọlu oun laipẹ yii niwaju ile ẹjọ giga to wa ni Iṣabọ, niluu Abẹokuta, ko ṣe lẹyin Gomina ọhun.

 

Ninu atọjade ti fi sita lọsẹ to kọja nibi to ti ki adele ọga awọn ọlọpaa naa ku oriire ipo tuntun ti wọn ṣẹṣẹ yan-an si lo tun lo akoko naa lati sọ fun Ẹgbẹtokun pe ko kilọ fun Dapọ Abiọdun, ko ki ọwọ ọmọ ọ bọ aṣọ,  lori awọn aṣekupani to fẹsun kan an pe o n lo.

 

O sọ pe ẹdun ọkan lo jẹ pe ẹni to yẹ ko jẹ olori alaabo nipinlẹ Ogun, tun ṣe onigbọwọ fawọn janduku. O ni iyalẹnu lo jẹ foun bawọn tọọgi ọhun ṣe doju ija kọ oun niwaju kọọtu giga to wa ni Iṣabọ, niluu Abẹokuta, laiṣe nnkankan fun wọn ju pe oun jẹ ọmọ ẹgbẹ oloṣelu alatako.

 

Ṣowunmi tun fikun ọrọ ẹ pe,’’ Mo ki Ẹgbẹtokun, ku oriire ipo tuntun gẹgẹ bi ọga agba patapata fawọn ọlọpaa lorileede yii, a si dupẹ lọwọ Aarẹ fun bo ṣe yan ọmọ ipinlẹ Ogun si ipo naa’’

 

‘’Ẹ jọwọ, mo fẹẹ pe akiyesi yin si iṣẹlẹ itiniloju to waye nipinlẹ Ogun, niluu abinibi wa, bi ọsẹ meloo kan sẹyin lawọn ọmọ ẹyin Dapọ Abiọdun yawọ ile ẹjọ giga, ni Iṣabọ, nibi tawọn ọlọpaa diẹ wa, ti wọn si lo awọn ọmọ garaji, ẹgbẹ okunkun lati wa da ibẹ ru, ti wọn si doju ija kọ awa alatako oloṣelu to wa nibẹ lọjọ naa’’

 

O tun ṣalaye siwaju pe gẹgẹ bi oun ṣe kọ lẹta si oludamọran pataki fun aarẹ lori ọrọ aabo lorileede yii, o ni itumọ nnkan ti Gominna ọhun ṣe nipa lilo awọn tọọgi tumọ si, o loun fẹẹ mu wa si iranti pe bi wọn ṣe bẹrẹ si nii ko awọn eeyan bẹẹ jọ nilẹ Hausa lori oṣelu to wa di nnkan ti wọn n ba awọn alumọni jẹ.

 

Ṣowunmi tun sọ pe, ‘’ Ṣe a le fi  gbogbo ipenija wa sọ pe Gomina Dapọ Abiọdun, to jẹ olori alaabo ilu n faye silẹ lati jẹ ki ipinlẹ naa gbona girigiri ati pe ṣe ipo ti ẹ wa lakooko yii ko ni aṣẹ lati ṣiṣẹ iwadii lori awọn to doju ija  kọ mi, ti wọn si fẹẹ gba ẹmi mi lojiji?

 

O waa rọ ọga ọlọpaa naa lati tete gbe igbesẹ lori ọrọ yii, ati pe awọn gbọdọ jọ ṣiṣẹ pọ lati rii pe wọn ko faye gba iru nnkan bẹẹ. Bẹẹ lo ṣeleri pe bi wọn ba fun oun laaye oun ṣetan lati fun wọn lorukọ ati nọmba foonu awọn janduku ti wọn n lo naa.

 

O ni inu alaafia nipinlẹ ọhun wa tẹlẹ ko to di pe Gomina bẹrẹ si nii lo awọn janduku yii.

 

 


No comments:

Post a Comment

Pages