Káyọ̀dé Sàlàkọ́ da ẹgbẹ tuntun silẹ PANFO lo n jẹ - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 13 May 2023

Káyọ̀dé Sàlàkọ́ da ẹgbẹ tuntun silẹ PANFO lo n jẹLọsẹ to kọja yii, Olukayọde Salakọ, to jẹ alaga fẹgbẹ oṣelu Labour tẹlẹ, nipinlẹ Eko, tun gbọna mii-in yọ, nigba ti wọn tun da ẹgbẹ tuntun ṣilẹ, ti wọn pe ni Passion Alliance Forum, PANFO, silẹ.

 

Nibi ifilọlẹ ẹgbẹ ọhun ni ọkunrin naa ti sọ pe awọn ṣe idasilẹ ẹ lati tubọ ṣagbega oṣelu ati pe erongba wọn ni lati le mu aṣeyọri ba a pẹlu lorileede yii.O ni ẹgbẹ  PANFO, yii yoo jẹ eyi ti wọn yoo maa fimọ sọkan gbe ero wọn jade kaakiri ipinlẹ Eko atawọn yooku ẹ.

 

Salakọ tun fikun ọrọ ẹ pe gẹgẹ bi awọn eeyan ṣe mọ pe oun ni alaga ẹgbẹ Labour tẹlẹ, toun si jẹ oludamọran pataki fun Agbẹjọro Julius Abure, to jẹ alaga ẹgbẹ wọn lapapọ, toun si ṣaaju igbimọ ẹlẹni mẹrinlelogun lati fi ṣatunṣe laarin oṣu marun-un. 

O ni, ‘’ Ọdun kan ni mo fi wa ninu ẹgbẹ Labour, gẹgẹ bi ẹ ṣe mọ pe mo kọwe fipo oludamọran pataki alaga silẹ ati ọmọ ẹgbẹ silẹ, nitori pe mi o le gbe ẹnu mi dakẹ,nnkan ti gbogbo yin si mọ ni’

 

Ẹgbẹ oṣelu Labour ati Obidient, ko figba kankan nigbagbọ ninu mi nigba ti mo jẹ alaga wọn, gbogbo igba ni wọn  fi maa n bu mi, nitori Tinubu, APC, ti wọn sọ pe mo waa gbabọde fawọn ni, eyi ni wọn ko jẹ ki n le ṣiṣẹ mi gẹgẹ bi ipo ti wọn yan mi fun’ 

O tun fikun ọrọ ẹ pe ti iyawo oun, Folukẹ Daramọla-Salakọ, to wa ninu APC, tun jẹ idi ti wọn fi n ba oun ja ni gbogbo igba naa.O ni wọn n wa ọna lati rii pe mo fi tipatipa muu wọnu ẹgbẹ Labour, nigba ti wọn ri i pe ko ṣee ṣe ni wọn ṣe n ba oun jẹ.

 

O ni nnkan ti wọn sọ ni pe ẹgbẹ oṣelu APC ati PDP ni ko dara, ṣugbọn ounle fi gbogbo ẹnu sọ pe ti Labour gan-an lo buru ju, ninu eyi tawọn araalu le jẹri si pẹlu. Ni bayii, o sọ pe iyapa ti wa ninu wọn laarin ipo olori apapọ ati alaga nipinlẹ Eko.

 

Nigba ti wọn sọ pe APC ati PDP ni iṣoro Naijiria, o ni bawo waa ni Labour naa yoo ti ri pẹlu bi wọn ṣe n ṣe yii. O ni niwọngba tawọn ti da ẹgbẹ tuntun silẹ, iyẹn PANFO, oun nigbagbọ pe ilọsiwaju ati igbega yoo de ba oṣelu lorileede yii.

 

O ni awọn to wa ninu ẹgbẹ tuntun ọhun lawọn ti figba kan jẹ ọmọ ẹgbẹ Labour nipinlẹ Eko, tawọn si ti ri bo ṣe n lọ nibẹ, awọn si ti pinnu lati kuro ninu ẹgbẹ ọhun, ibi tawọn ba si n lọ, awọn yoo maa fi to awọn eeyan leti.

 

Salakọ ni,’’ A ṣetan lati maa ṣakoso PANFO, pẹlu igbmọ mẹtalelọgbọn, eyi ta a maa fi orukọ ẹ silẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu lorileede yii, bo tilẹ jẹ pe ko ti i ju oṣu meji lọ ti a da silẹ’’.

 

Lara awọn oloye ẹgbẹ  naa ni Olukayọde Salakọ to jẹ alaga ẹgbẹ, Ọnarebu Ọmọtayọ Oyindọlapọ Elizabeth, igbakeji alaga, Ọnarebu Kazeem Owoyẹle, akọwe ẹgbẹ, Dokita Adeyẹmi Idowu, igbakeji alaga fun iṣẹ akanṣe, Dokita Babatunde Fatoke atawọn yooku.

 

 

 


No comments:

Post a Comment

Pages