Sefiu foko oro ranse: O ni pinpin lowo Yayi - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday 1 February 2023

Sefiu foko oro ranse: O ni pinpin lowo Yayi



Fun opo iseju ni ariwo fi gbale nibi ipolongo ti Agbejoro Olubiyi Otegbeye, oludije fun ipo gomina labe egbe oselu ADC, se niluu Abeokuta, nigba ti gbajumo olorin fuji nni, Sefiu Alao fi oko orin ranse si Seneto Solomon Adeola, to n dije fun ipo seneto ni Ogun West, to ni pinpin lowo Yayi.

Nibi ipolongo naa ni okunrin yii ti je plan lara awon olorin ti won pe lati wa da awon eeyan laraya.

Sefiu Alao nigba to koko korin lo ti bi enu ate lu ijoba Dapo Abiodun to wa lode nipinle Ogun, gege bi eyi to ni awon araalu lara.

O so ninu orin e pe opo ise ti Ibikunle Amosun se nigba to wa nijoba ni Dapo Abiodun ti baje, o waa gba awon araalu lamoran lati fi ibo won gbe Otegbeye wole gege bi gomina.

Nigba to ya lo yi orin naa biri, to foko oro ranse si Yayi pe pinpin lowo e kawon ara Ogun West tete lo gba ti won. O ni pinpin lowo Yayi, ki won je ki won na.

Se ni ariwo gba gbogbo ibi ipolongo naa, a fi bigba ti won ti n reti iru orin bee, ti won si n ko kaakiri.

No comments:

Post a Comment

Pages