Ojogbon Asiwaju gba Otegbeye lamoran lori awon ise akanse ti won pa ti ni Ogun West - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 11 February 2023

Ojogbon Asiwaju gba Otegbeye lamoran lori awon ise akanse ti won pa ti ni Ogun WestOjogbon Anthony Asiwaju, okan lara awon akinkanju agba nile Yewa ti gba Biyi Otegbeye, oludije gomina labe egbe oselu ADC, nipinle Ogun, nimoran lati rii pe gbogbo awon ise akanse ti won pa ti nile Yewa, ni ko rii pe o sise le lori, ti won ba dibo yan an wole.

Baba agbalagba yii soro naa ni afin Onimeko lakooko ti ADC, gbe ipolongo won de ijoba ibile Imeko Afin.

Nigba ti okunrin naa n ko awon iwe meji lara to se fun Otegbeye lo ti ro lati lo ka iwe naa, ti yoo si se atona e, nipa awon nnkan ti yoo lo se ni Oke-Mosan.

Ojogbon naa fikun oro e pe" Opo awon ise akanse ti won pa ti nile Yewa Awori lo fe je eyi to se pataki. Lo si Ipokia, ileewe poli to wa nibe, won ko se nnkankan si.Bi e ba si tun wo gbogbo awon ona wa, ko sigba ti omi ki nii bo loju e, nitori bi ipo ti won wa ko se bojumu to.

Bakan naa ni Asiwaju so pe o ti to odun metadinlaadota tipinle Ogun ti wa, Ogun West ko ti di gomina ri, eyi to so pe atunse yoo de ba laipe.

O waa gbadura pe gege bi won se Fe ki Ogun West dije fun ipo gomina lakooko yii, Olorun yoo je ko ri be.

Ninu oro Otegbeye, lo ti ro Asiwaju lati kopa to joju gege bi won se maa n se tele,o ni awokose tawon n wo niwaju ni okunrin naa ati pe ninu itan Yewa, Ipa e ko se gbagbe.

 Bee lo so pe itan ko nii gbagbe pe Yewa Awori jade lati dupo gomina lakooko tawon eeyan so pe o ti to.

 O ni "Ibeere kan soso ni pe ta ni o fee duro ti, ti yoo si tun gba enu e soro,mo n fe atileyin Ari ohun yin lakooko yii, mo si mu da yin loju pe a maa jawe olubori, gbogbo amoran yin ni mo si maa tele.
No comments:

Post a Comment

Pages