Inu mi dun lati gba ẹ lalajo gẹgẹ bi ojulowo ọmọ- Oliiworo of Iworo* - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 3 February 2023

Inu mi dun lati gba ẹ lalajo gẹgẹ bi ojulowo ọmọ- Oliiworo of Iworo*


Oliworo tilu Iworo nijọba ibilẹ Ijebu North East, nipinlẹ Ogun, Ọba Gabriel

Adebisi Ọnafuwa, ti kan ṣapejuwe Agbẹjọro Biyi Ọtẹgbẹyẹ, oludije gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress, ADC,  gẹgẹ bi ojulowo ọmọ Iworo. O sọ pe o tipẹ toun ti gbọ nipa oludije ọhun, inu oun si dun lati mọ ọn.

 

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, Odopotu ni wọn ti bi Mama to bi Ọtẹgbẹyẹ ti wa nigba ti mama to bi mama ẹ wa lati Iworo.

 

Nigba to n sọrọ bi o ṣe maa n lo igba ewe ẹ ni Iworo, Ọtẹgbẹyẹ sọ pe ọpọ ma ni gbagbe loun ṣe lakooko naa. O waa ṣeleri pe oun yoo mu idagbasoke ba ọrọ aje wọn nibẹ ati pe akoko ti to lati gba awọn obinrin agbegbe naa kuro iṣẹ aṣeelaagun wọn.

 

Otẹgbẹyẹ sọ pe " Ohun tijọba wa fun lati sin awọn eeyan ni nnkan ti wọn n fẹ, ṣugbọn o bi a ba ni ka sọ nipa ijọba to wa lode oni, ko ri bẹ fun wọn, gbogbo nnkan wọnyii si ni atunṣe yoo de ba lati mu igbe aye irọrun bawọn eeyan wa.

 

'' A maa rii pe ọrọ aje ti yoo mu idunnu fawọn eeyan wa ṣe pataki fun wa bẹẹ ni awọn obinrin yoo gbagbe owo ele, Awọn ọna wa yoo gun rere ti mọto yoo ṣe gba lati lọ ṣiṣẹ agbẹ wa. Ẹ ẹ ma jẹ ko ya yin lẹnu pe ibi yii ni mo ti ṣe kekere, emi ni mo maa n lu aago isin ni ṣọọṣi to wa ni Iworo nibi. Ile ni mo wa, nitori mama to bi mama mi, ibi yii naa lo ti wa'

 

Ko to to akoko yii, Ọtẹgbẹyẹ ti ṣaaju awọn ikọ ẹ lọ sọdọ Ọba Adebayọ Okubena, the Elerunwọn ti Eruwọn,nibi ti Kabiyesi ti ṣadura fun oun ati igbakeji ẹ, iyẹn Alaaji Tunde Awonuga.

 


No comments:

Post a Comment

Pages