Ayipada rere yoo de ba awon ijoba ibile ti mo ba wole gomina- Otegbeye - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday 9 February 2023

Ayipada rere yoo de ba awon ijoba ibile ti mo ba wole gomina- Otegbeye





Oludije Gomina labe egbe oselu ADC nipinle Ogun, Agbejoro Olubiyi Otegbeye,ti seleri pe ayipada rere yoo bere si ni de ba awon ijoba ibile to wa nipinle Ogun, bi won ba le dibo yan oun gege bi gomina ninu ibo ti yoo waye lojo kokanla osu keta odun yii.

Okunrin naa soro yii lakooko to sabewo lo si afin Olu tilu Igbein, Oba Festus Oluwole Makinde, nigba to gbe ipolongo e lo si ijoba ibile Obafemi Owode.
 
O so pe pataki lawon ijoba ibile je ninu mimu idagbasoke ba awon eeyan igberiko iyen ti won ba fun won laaye lati se ojuse won gege bi ofin ti la a sile.


O sakiyesi isaloso ijoba ibile ko ri bo se ye ko ri ninu isejoba to n lo lowo nipinle Ogun, nitori pe gbogbo eto won nijoba ipinle ti gba a tan, ti ko si je ki won maa se ojuse won gege bi ofin se so. 

Otegbeye tun so pe ijoba to ko gba sile ki Dapo Abiodun to gba se idasile ijoba ibile onidagbasoke iyen lati le tan kale isejoba de awon eeyan to n gbe ni igberiko sugbon ti ijoba to wa lode yii gbese le won.

O ni oro enu ko ijoba yii ti ba nnkan je lawon ijoba ibile, ko si nnkan mi to so pe o fa bi ko se pe won fe maa gbakoso inawo, ko le maa bo sapo won.

 Otegbeye tun so pe, "Gbogbo nnkan ti won se lati le je kawon ijoba ibile maa se ojuse won gege bo se to ati bo se ye nijoba yii ti pare.Nnkan ta a kan n ri bayii ni pe owo to ye ko wole si osuwon ijoba ibile lati odo ijoba apapo ni tipinle n gba,ohun to buru ju gba a ni. Mo so lose to koja, mo tun maa tun so lonii pe Ina apa ni fun ijoba lati na bilionu naira lati fi ko City Gate, nigba ti iru owo bee se na fun kiko ileewe ati Ile itoju""

O waa mu dawon loju pe gbogbo ona loun yoo sa lati da ogo awon ijoba ibile pada bee lopo awon imayederun yoo tun wo ilu atawon agbegbe .

Ko to akoko naa ni Otegbeye ti koko so ni afin Olu Siun, Oba Lawrence Adisa Odeyinka, pe ijoba to n bo yii ko ni wa fun atunse lasan bi ko se pe yoo tun mu igbega lawon ise tawon to ti je gomina tele se, awon bii Oloye Olabisi Onabanjo, Oloye  Olusegun Osoba, Otunba Gbenga Daniel ati Senato Ibikunle Amosun.

No comments:

Post a Comment

Pages