Oriire meji lojo kan soso fun Otegbeye - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Monday 23 January 2023

Oriire meji lojo kan soso fun Otegbeye
Beeyan ba gun esin ninu Agbejoro Olubiyi Otegbeye, oludije gomina labe egbe oselu ADC, ko nii kose fun oriire meji otooto to waye fun un lonii.

Nitori bo se n dunnu fun ayeye ojoobi iyawo e, Iyaafin Ronke Otegbeye bee naa lo tun jawe olubori ninu igbejo kotemilorun to waye niluu Ibadan.

Ninu idajo Onidajo M A Adumen, tile ejo kotemilorun naa lo ti so pe egbe oselu APC ati Labour ko lase labe ofin lati pe ADC lejo tabi da si nnkan to n lo ninu egbe naa.

Bakan naa lo so pe bi won se pe ejo pe ki ajo eleto idibo INEC yo oruko awon eeyan naa kuro gege bi oludije fegbe oselu ADC ko lese nile.

O so pe awon oludije ninu egbe oselu naa lo ni ase lati pe ara won lejo ki i se lati ita, o ni bigba teeyan ba n se ayonuso loun ka  a si, nitori naa o wogi le ase Ile ejo to koko waye ni Abeokuta.

Koda o tun ni ki won san egberun lona aadota naira gege bi owo itanran.


No comments:

Post a Comment

Pages