Egbe oselu Labour ko yoju nibi igbejo kotemilorun ti Biyi Otegbeye ADC pe. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday 11 January 2023

Egbe oselu Labour ko yoju nibi igbejo kotemilorun ti Biyi Otegbeye ADC pe.



Adajo ile ejo kotemilorun to wa ni Ibadan ti so pe ko nii pe ko nii jimna ti idajo yoo waye lori ejo ti Ile ejo giga kan niluu Abeokuta, da lati fi tako oludije fegbe oselu ADC, Agbejoro Biyi Otegbeye atawon oludije omo Ile igbimo asofin.

Ninu igbejo naa to waye lonii, eyi to pin si ona meji, akoko ni ti egbe oselu Labour ipinle Ogun ati Agbejoro Olubiyi OtegbeyeOtegbeye, nigba ti eleekeji je egbe oselu APC atawon oludije merindinlogbon omo Ile igbimo asofin labe ADC.

Lojo kokandinlogbon, osu kokanla, odun to koja,ni Onidajo Akintayo Aluko, to n gbejo naa da ejo yii ninu eyi to ti pase pe ki ajo INEC, yo oruko Otegbeye atawon oludije omo Ile igbimo asofin labe ADC kuro ninu awon oludije ti yoo kopa ninu ibo to n bo.

Sugbon nibi igbejo kotemilorun to waye lonii, bawon agbejoro APC, se wa nile ejo,won ko ri ti Labour ko yoju rara titi won fi pari igbejo naa.

Gege bi iwe ipejo naa se ka,"Ninu ejo to waye laaarin Olubiyi Otegbeye ati Labour, to waye nile ejo kotemilorun ni Ibadan, niwaju Onidajo Moore Aseimo Abraham Adumein, awon asoju egbe oselu Labour, ko yoju.

Agbejoro to wa duro fun Otegbeye ati ADC, wa fi igbejo to n lo lowo naa we ti Rivers PDP ati APC, eyi ti won so pe awon to pe ejo naa ko lase lati pe nitori won ki i jo somo ati  omo egbe nikan ninu ADC, lo lase lati pe ejo ki i se lati ita.

Pelu gbogbo e sa, Onidajo Moore Aseimo,to wa so pe ki won si maa lo sile won, oun yoo kan si won nigba ti idajo yoo ba waye.

No comments:

Post a Comment

Pages