Biyi Ọtẹgbẹyẹ ṣe ariya ọdun fawọn ọmọde niluu Ilaro - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 1 January 2023

Biyi Ọtẹgbẹyẹ ṣe ariya ọdun fawọn ọmọde niluu IlaroLati le mi inu awọn ọmọde dun fun ọdun tuntun, oludije Gomina fẹgbẹ oṣelu ADC, nipinlẹ Ogun, Agbẹjọro Olubiyi Ọtẹgbẹyẹ da ariya rẹpẹtẹ silẹ fawọn ọmọde niluu Ilaro,

Ariya ọdun naa, ẹlẹẹkejidinlogun ọhun, to waye lanaa, lọjo ọdun tuntun lawọn ọmọde yii ti wa jakejado lati wa ba oludije gomina ọhun ṣọdun pẹlu idunnu ati ayọ.Ṣe ni ẹsẹ o gbero fawọn ọmọ naa, nibi ti wọn ti jẹun, ti wọn mu, ti wọn si tun jo ijo ọdun pẹlu Biyi Ọtẹgbẹyẹ, bẹẹ ni wọn tun mu ẹbun ọlọkan-ọ-jọkan lọ sile pẹlu.

Ninu ọrọ Agbẹjọro Olubiyi Ọtẹgbẹyẹ lọjọ naa, lo ti kọkọ dupẹ lọwọ Ọlọrun fun pe o da awọn ọmọ naa si lati ri ọdun tuntun ati pe idi pataki toun fi maa ṣariya fawọn ọmọ naa ni lati fi ẹmi imoore han.

O sọ pe gbogbo wa la mọ pe pataki lawọn ọmọde jẹ, koda Bibeli sọ fun wa pe ọmọ ni ini Oluwa, ọmọ Ọwọ si ni ere ẹ, bi ọfa ti ri lọwọ alagbara bẹẹ lawọn ọmọde ri.O waa gba awọn ọmọ naa nimọran lati maa wulo fawọn obi wọn, bẹẹ ni ki wọn jẹ awokọṣe rere fun ẹbi ati orileede.

Bakan naa lo ṣeleri pe lọdọọdun ni iru nnkan bẹẹ yoo ma waye gẹgẹ bi oun ṣe n ṣe tẹlẹ.

Awọn ọmọ naa fun fi ẹmi imoore wọn han si Ọtẹgbẹyẹ fun ariya ọdun to ṣe fawọn, bẹẹ ni wọn tun rọjo adura le e lori pẹlu.


No comments:

Post a Comment

Pages