Adajo ni ki Udeze san milionu kan naira nitori o pe ara e ni alaga Action Alliance. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday 11 January 2023

Adajo ni ki Udeze san milionu kan naira nitori o pe ara e ni alaga Action Alliance.Adajo Ile ejo giga kan niluu, Abuja, Onidajo Binta Nyako, ti pase pe ki Kenneth Udeze, San milionu kan naira gege bi owo itanran nitori bo se n pe ara e ni alaga apapo fegbe oselu  Action Alliance (AA).

Ninu idajo to waye lojo Tusidee, ana, ni Adajo naa ti pase fun agbejoro Udeze, iyen S.C. Uchendu, ati onibaara e lati jumo jo san owo naa.

Gege bi a se gbo, Udeze ati Vernimbe James, ni won pe ejo kan ti nomba e he FHC/ABJ/CS/1871/2022, nibi ti won ti ro Ile ejo loruko egbe oselu AA, lati tako ajo eleto idibo INEC.


Ninu ejo to waye lojo kejidinlogbon, osu kokanla, odun 2022, lawon eeyan yii nipase agbejoro won ni Udeze ti so pe oun ni ojulowo alaga  egbe naa nigba ti James naa ni oun ni akowe. 

Nibi igbejo osu kokanla, odun to koja naa, ni won  ti so pe o ye ki won pe awon naa,nitori pataki ni won ninu egbe.

Nigba ti won gbe awon oro naa yewo lona mejila ni won ti so pe ejo naa ko le niyanju laije pe awon ba wa nibe.

Sugbon agbejoro fegbe oselu AA,
Oba Maduabuchi, lodi si kawon olupejo naa darapo mo won.O so pe ona kan pataki to le mu ki egbe pe apapo ni to ba je pe Ile ejo ko nii segbe fegbe naa.Amo ti iru nnkan bee ko ba ni waye,o ni ko pon dandan 

Agbejoro naa so pe ninu ejo to wa nile yii igba meta otooto ni Udeze ti n pe ara e ni alaga sugbon to je Ile ejo meta otooto ni won ti so pe ki i se 

Nigba ti Nyako gbe idajo e kale, o ni awon eri to wa niwaju oun fihan pe paapaa julo tile ejo kotemilorun fi han daju pe Udeze ki i se omo egbe AA mo ati pe won tii da a duro,koda won ti le danu.

O so pe bi okunrin naa se tun pe ara e ni alaga egbe naa ko bojumu,o waa pase pe ki oun ati agbejoro e san milionu kan naira gege bi owo itanran, to si sun igbejo siwaju do ojo kerindinlogun,osu yii.


No comments:

Post a Comment

Pages