Ọnarebu Rotimi Ogundele, oludije ọmọ ile igbimọ aṣofin labẹ ẹgbẹ oṣelu African Democratic Party, ADC, fun agbegbe Yewa South, ninu ibo to n bọ yii ti rọ gbogbo awọn ọmọ orileede yii ki wọn nireti pe ayipada rere si n bọ wa ba orileede yii, bi a ṣe n murasilẹ fun eto idibo gbogbogboo lọdun tuntun yii.
Ọnarebu naa sọrọ yii ninu iṣẹ to ran to fi ki awọn eeyan fun ti ọdun tuntun ta a ṣẹṣẹ mu yii. O sọ pe fifi ifẹ han sawọn to ku diẹ kaato fun lakooko ọdun tun jẹ ara ero rere. Bẹẹ lo rọ awọn araalu lati dide iranlọwọ si ara wọn.
O fikun ọrọ ẹ pe bi a ṣe mọ pe ọdun 2022 jẹ ipasẹ irinajo oṣelu, to si jẹ ọpọ ipenija la ti n koju
ti Ọlọrun si mu wa bori, koda, o ni pẹlu atilẹyin awọn ọmọlẹyin wọn, awọn ṣe aṣeyọri akanṣe fun Irọrun de 2023, iyẹn akanṣe iṣẹ nla fun ẹgbẹ oṣelu ADC, lọdun ta a ṣẹṣẹ lo tan yii.
Ọnarebu Ogundele tun fikun ọrọ ẹ pe, ‘’ Gẹgẹ bi a ṣe nireti ti a si nigbagbọ pe igbẹjọ kotẹmilọrun to n bọ laipẹ yoo gbe wa, ṣugbọn awa naa ko gbọdọ sinmi tabi kaarẹ, titi ti ẹtọ wa yoo fi tẹ wa lọwọ’’
‘’ Ẹ jẹ ki gbogbo ilodi si wa maa bọ ọdun 2022, lọ ki a si kọ bi a ṣe maa koju ipenija fọdun 2023,Ki a ṣe ọdun naa pẹlu ayọ ati idunnu. Mo si nireti pe ọgun tuntun yii yoo mu ibukun ati oriire nla ba gbogbo awọn eeyan agbegbe Yewa South, ti mo fẹẹ lọ ṣoju fun’’
No comments:
Post a Comment