Ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress (ADC), ipinlẹ Ogun, ti ke gbajare lori bi wọn ṣe ni Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọbọ Dapọ Abiọdun fẹẹ lo ọwọ agbara lori awọn ẹgbẹ oṣelu alatako lori.
Sẹnetọ Iyabọ Anisulowo, lo sọrọ naa lakooko ti wọn fi aidunnu wọn han lori igbesẹ ti Gomina ọhun gbe lati ma jẹ ki ipade to yẹ ko waye laarin Ọlọta tiluu Ọta, Ọba Adeyẹmi Abdulkabir Ọbalenge atawọn ọba ilẹ Awori, pẹlu Olubiyi Ọtẹgbẹyẹ, oludije gomina fẹgbẹ oṣelu ADC, nipinlẹ naa.
Nibi ipade oniroyin to waye ọhun ni wọn ti sọ pe ipade ọhun to yẹ ko waye lonii, ti wọn si ti wa ni imurasilẹ lo fori sanpọn.
O ni idi ti wọn ko fi jẹ ki ipade ọhun waye si n jẹ iyalẹnu fawọn laisọ pe nnkan bayii lo ṣẹlẹ.
Anisulowo sọ pe itiju ati ẹdun ọkan lo jẹ pe awọn ọba alaye ti wọn wa nikawọ aṣa ni Gomina Abiọdun tun fẹẹ fọwọ oṣelu muu mọlẹ. O ni igbesẹ yii tun mu ijakulẹ ba ẹgbẹ oṣelu APC patapata.
O ni eyi to jẹ ki ọrọ naa tun buru ju aṣilo agbara to ni Dapọ Abiọdun, lo ni Ogun West, lati ma jẹ ki awọn ọba alaye Yewa-Awori, ma gba ọmọ wọn lalejo lori ilẹ wọn.
Aniṣulowo tun fi kun ọrọ ẹ pe’’ Gomina to dena ọmọ Yewa- Awori lati ma ri awọn ọba ẹ lo wa ni Ijẹbu pẹlu awọn ọba Ijẹbu, to si tun ti lọ kaakiri ipinlẹ Ogun.
O waa pari ọrọ ẹ pe awọn ko ni gba gbogbo ero ti Abiọdun ba ni lati fi pa awọn alatako nipinlẹ Ogun.
No comments:
Post a Comment