APC ti su wọn nipinlẹ Ogun, ADC ni yoo wọle lọdun 2023 -Olurotimi Ogundele
Bi nnkan ṣe n lọọ yii, afaimọ ki ẹgbẹ oṣelu APC, nipinlẹ Ogun, ma fidirẹmi ninu ibo gomina to n bọ lọdun to n bọ, nitori bawọn araalu ṣe n jade sita, ti wọn bu ẹnu atẹ lu Gomina Dapọ Abiọdun, lori bo ṣe mu inira bawọn araalu lakooko iṣejọba ẹ.
Lọsẹ to kọja yii, ni Ọgbẹni Jacob Olurotimi Ogundele, tọpọ awọn eeyan mọ si Political Solution, oludije ọmọ ile igbimọ aṣofin nipinlẹ Ogun, fun ẹkun Yewa South, labẹ ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress, ADC, sọ pe aini igbaradi Gomina ọhun lati depo to wa yii, lo jẹ ko mu ijakulẹ ba araalu, toun si mọ pe o ti n lulẹ bayii.
Ọkunrin naa tun sọ pe oludije kan soso tawọn mọ pe Ọlọrun ṣetan lati gba ọmọ ipinlẹ Ogun silẹ, ninu ibo to n bọ naa ni agbẹjọro Olubiyi Ọtẹgbẹyẹ, tawọn jọ wa lati agbegbe kan naa, oun lo si tun fa oun kalẹ, to ni oun koju oṣuwọn lati ṣoju awọn eeyan Yewa South, nile igbimọ aṣofin to n bọ.
O sọ pe ọrọ ibo to n bọ yii ko nii ṣe pẹlu ẹgbẹ oṣelu, bi ko ṣe awọn ipa toun ti ko sẹyin lo jẹ kawọn ara agbegbe ohun sọ pe ibi yoowu toun ba ti jade awọn ṣetan lati ṣatilẹyin foun. O ni awọn gan-an lo gbe oun jade.
Olurotimi Ogundele tun ṣalaye siwaju pe bi wọn ba sọ nipa ti iwe awọn obi oun tiraka le oun lori, lati ileewe alakọbẹrẹ titi di iwe giga patapata toun si gba imọ ijilẹ lori awọn ẹkọ bi wọn ti n ṣayewo ẹjẹ iyẹn Science Labouratory Technology, bakan naa lori imọ kọmputa.
O ni, ‘’Iṣẹ asofin, ọna meji ni wọn la a si, ṣugbọn gẹgẹ bi inagijẹ ti wọn fun mi iyẹn Poltical Solution, ọna mẹta ni mo maa ya si ni temi, ti mo si maa ṣiṣẹ le lori ti wọn ba dibo yan mi wọle. Akọkọ ni pe ofin faye gba, ko lọọ sofin to maa mi idẹrun bawọn araalu.ẹlẹẹkeji ni aṣoju, bi a ba feeyan jẹ aṣoju, o gbọdọ maa ṣe abojuto bi nnkan ba ṣe n lọ ni agbegbe ẹ ati ẹlẹẹkẹta, to jẹ temi, mo gbọdọ wa ọna lati wa owo ti waa fi ma ro awọn eeyan mi lagbara’’.
Lori igbaradi ẹgbẹ oṣelu ADC, Ọkunrin naa sọ pe awọn ti wa nigbaradi, nitori awọn araalu gan-an ti foju sọna ki ọjọ idibo pe, ki wọn le fi ibo wọn gbe waa wọle, o ni apẹẹrẹ iru eyi waye, bi wọn ba bawọn eeyan Ogun Waterside, ṣe tu jade lati waa pade ọmọ won, to fẹẹ ṣe igbakeji gomina iyẹn Tunde Awonuga.
O tun ṣalaye siwaju pe ‘’ Emi ni ore ọfẹ pe lakọọkọ, ti mo fẹ dije gbangba ni ti ọmọ ile igbimọ aṣofin niyi. Loootọ, mo ti n jade fun ipo tẹlẹ, nitori mo ti wa ninu oselu tipẹ, o ti le ni ogun ọdun sẹyin. Gbogbo ilu lo pawọpọ to ni ki n jade dupo, awn ilu lo tẹle mi, Biyi Ọtẹgbẹyẹ ni yoo si wọle nitori awọn araalu n wa ọna abayọ si ọrọ Dapọ Abọdun. wọn si ri pe oun lo kaju ẹ, to ti wa ni imurasilẹ lati di gomina.
No comments:
Post a Comment