Gomina ipinle Ogun, Omooba Dapo Abiodun, ti sapejuwe Asofin Solomon Adeola, topo mo si Yayi, gege bi ojulowo omo bibi ipinle Ogun, to n gbe e laruge nibi gbogbo.
O soro naa nibi ayeye iweje-wemu ti won se fun Asofin to n soju ipinle Eko, lowolowo bayii niluu Abuja, to tun wa je oludije asofin fun Ogun West, ninu ibo to n bo lodun 2023, fun ti ami eye OON, ti Aare orileede yii, Mohammadu Buhari,fi da a lola.
Nibi ayeye ohun lawon eeyan jakanjakan nipinle Eko ati Ogun, ti peju pese, O so pe pelu awon ise akinkanju ti okunrin naa ti se tawon foju ri lati mu idagbasoke ba ilu ati igbe aye omoniyan ti fihan pe oloselu, to se e muyangan omo bibi ipinle Ogun ni, tawon si ni igbekele ninu e.
Gomina wa so pe loruko gbogbo omo ipinle Ogun to n sejoba le lori, oun ki Asofin naa ku oriire fun ami eye nla to gba.
O so pe " Gbogbo nnkan ta a n ri yii fihan pe Asofin wa n tele igbese awon akinkanju eeyan bii Pa Awolowo, Oloye MKO Abiola, Ojogbon Wole Soyinka, Ogagun Olusegun Obasanjo, Ojogbon Yemi Osinbajo. O si da mi loju pe awon ibi giga kan si wa, to n lọ nigbe aye e"
Dapo Abiodun tun salaye pe loooto ki i se pe oun wa polongo amo beeyan ba ri ooto, o ye ko so gege bi Omooba, Yayi ni yoo wole gege bi asofin wa ninu ibo to n bo.
Ninu oro Oba Kehinde Olugbenle, Olu tilu Ilaro, o sakiyesi pe gbogbo awon oludije meteeta fun ipo asofin labe egbe oselu APC nipinle Ogun, ni won wa nibi apeje naa, o wa ni ki won fi okan won bale nitori awon eeyan ipinle Ogun yoo fi ibo gbe won wole.
Gbogbo awon to tun soro nibe ni won ki Yayi ku oriire ami eye naa, won ni o to si nitori awon ise to ti se.
Ninu oro Asofin Solomon Adeola, o dupe lowo gbogbo awon to waa ye e si lojo naa, eyi ti won tun fi gba oun niyanju lati tesiwaju ninu awon ise to n se nipinle Ogun.
Lara awon to wa nibe ni Igbakeji Gomina nipinle Ogun, Noimot Oyedele- Salako,Otunba Gbenga Daniel Omooba Segun Adesegun, Otunba Femi Pedro ati awon olori Ile igbimo asofin tele nipinle Ogun, Tunji Egbetokun ati Suraj Adekumbi .
Bee naa ni Olu Ilaro, Oba Kehinde Olugbenle, ati Oba Abdulkabir Obalanlege, Olota tiluu Ota pelu awon oba marun-un mii-in lati Ota wa nibe.
No comments:
Post a Comment