Gbogbo
aheso eyi to tii n j anile lati bi odun meloo kan seyin pe oludije fun ipo
gomina labe egbe oselu UPN lodun 2015, Otunba Rotimi Paseda fee fegbe naa sile
darapo mo egbe mi in lo ja si ooto bayii, nitori bi a se n soro yii, abe egbe
oselu SDP lokunrin naa yoo ti jade dupo lodun to n bo.
Gege bi a
se gbo, gbogbo eto lo ti pari bayii ati pe laipe yii lokunrin naa yoo jade sita
gbangba lati kede erongba e fegbe oselu tuntun naa.
Ohun ta gbo pe o mu ki okunrin naa darapo mo
egbe oselu SDP ni bi won se ni awon erongba e se ba ti egbe naa mu. Bakan naa
la gbo pe won ni okunrin nigbagbo ninu egbe naa pe ibe loun ti le mu ala oun se
lori ati so ipinle yii di tuntun.
No comments:
Post a Comment