Bi o ba je pe bawon eeyan se tu yaya jade wa sibi ayeye
ojoobi ti won se fun oludije fun ipo gomina nipinle Ogun labe egbe oselu APC,
Seneto Solomon Olalekan Adeola ti won n pe ni Yayi ni won se bee dibo, ti won
si tun tan ihinrere okunrin naa jakejado o da ni loju pe ko ni si wahala kankan
mo nigba ti ibo naa ba de.
Nitori pe ese o gbero nile okunrin naa to wa niluu
Ilaro nibi tawon ololufe e ti se ayeye ojoobi to larinrin naa fun un. Bo tile
je pe won ni okunrin oludije naa ko si nile, won lo rin irin ajo loo si orile
ede America, sugbon sa, won ko je kawon eeyan mo ala pe ko si nile.
Ariwo Yayi, Yayi lawon to wa nibe n pariwo pe peluu
adura pe nigba ti yoo ba fi di iwoyi odun 2019 nile Ijoba ni Yayi yoo wa gege
bi gomina lakoko to ba tun fee se iru ojoobi bee.
Ninu oro Onarebu Kunle Adesina to je alaga fegbe oselu
APC ni aarin gungun Ogun, iyen Ogun Central, o so pe ko si owo oludije naa
kankan ninu inawo ti won se lojo naa, o lawon ololufe e, ni won se e fun un
lati fi yaa lenu.
O salaye pe Yayi je omo buje bu danu, to si maa n ran
awon eeyan lowo, idi niyii to fi je pe ojooojumo lawon omo leyin e po si.Bakan
naa lo so tun so peTekobo loun naa tele,ko to di pe won pe oun wa dupo oselu,
toun si wole, amo boun se wole bayii loun ti di Baba Legba.
Bakan naa lo so pe ti Yayi naa maa ri, ni nnkan bi
ogun odun sakoko yii, leyin ti okunrin naa ba ti wole sipo gomina, ko ni pada
di Tekobo mo, Baba ni Ilaro ni won yoo maa pe.
Okunrin naa tun tesiwaju pe gbogbo ipa ti Yayi ti ko
nipinle Ekoo, nibi to ti di ipo oselu muu lati nnkan bii odun merinla ju bee
loo seyin,lawon eeyan kan ri ti won fi so pe ki o wa dije nipinle Ogun, o ni
bawon ko ba sora, won yoo gba mo awon lowo patapata ni.
Lori pe Yayi kii somo Ilaro to ni awon kan n gbe
kaakiri, okunrin naa so pe igba akoko ko ree ti won yoo so iru e, o ni won so
iru nnkan bee si Oloye Olusegun Osoba lodun 1990 nigba to koko fee dupo gomina
ti won so pe omo Osogbo ni.
O ni se eni to ba sise niluu okeere to bimo sibe, ko
gbodo pada silu e mo, o ni niwogba ti ofin ile wa ko ba ti tako,wahala ti won
ni. Bee lo tun so pe eegun ile Yayi to jo lojo naa, o ni kii se eegun lasan, o
ni ka ni Adeola kii ba somo ilu naa ni, gbogbo nnkan tawon eegun naa se lojo
naa, won ko ni le se.
Bakan naa lawon oloselu min in naa tun soro imoriya
lojo naa, leyin naa ni won ge akara oyinbo fun ayeye ojo naa. Olorin Juju nni
Wole Papa lo fere da awon eeyan lara ya lojo naa.
No comments:
Post a Comment