Gẹgẹ bi a ṣe gbọ ti wọn n gbe kaakiri wọn ni obinrin naa ko mọ ibi ti ọrọ naa yoo ja si ko ma baa di itiju fun un lo ṣe ba ẹsẹ ẹ sọrọ pada si oke okun nibi to n gbe tẹlẹ.
Lati bi ọsẹ meloo kan sẹyin ti aṣẹ ile ẹjọ giga julọ ti paṣẹ lori ofin idibo ilẹ wa ti ẹka kẹtadinlọgọrin, ẹsẹ kẹta, kẹrin, ikarun ati kẹfa, eyi to sọ pẹ ẹnikẹni ti orukọ ẹ ko ba si ninu iwe gẹgẹ bi ọmọ ẹgbẹ ti wọn fi ṣọwọ si ajọ eleto idibo, ko le kopa gẹgẹ bi oludije fẹgbẹ oṣelu kankan lorileede yii.
Eyi lo faa tawọn oloṣelu kan fi foko ọrọ ranṣẹ sawọn oludije kan pe awọn lo n ba wi, ninu ẹ naa ni Iyabọ Ọbasanjọ wa, bo tilẹ jẹ pe ile ẹjọ ọhun ko darukọ kankan.
Idi niyii ti wọn fi gbe ahesọ kaakiri pe obinrin naa ti sa kuro niluu nitori itiju.Ṣugbọn ni bayii, Ọgbẹni Ayọ Arowojolu, to jẹ akọwe iroyin fun Iyabọ Ọbasanjọ ti sọ pe irọ pata ni ati pe ko soootọ ninu ọrọ naa.
O ni lana an ṣi ni ajọ eleto idibo gbe orukọ awọn oludije jade ti Iyabọ Ọbasanjọ ṣi wa ninu wọn.
Ati pe igba akọkọ kọ ree, ti Sẹnetọ Iyabọ Ọbasanjọ maa n lọ si oke okun to si maa n pada, nitori idi eyi ko ṣa lọ.
Amọ sa, awọn kan sọ pe otitọ yoo farahan laipẹ.
No comments:
Post a Comment