Irẹjẹ lo mu mi kuro ninu egbe APC - George Taylor - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday, 20 October 2026

Irẹjẹ lo mu mi kuro ninu egbe APC - George Taylor

George Taylor, oludije fun ipo sẹnetọ fun ẹkun Ogun Central labẹ ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress, ADC, nipinlẹ Ogun ti sọ pe irẹjẹ lo mu oun kuro ninu APC.

O sọrọ yii lakooko to n kopa lori eto ori redio kan,gẹgẹ bo ṣe wi, o ni APC ti wọn pariwo ẹ lakooko yii, awọn lawọn ni laye Oloogbe Ṣẹgun Taiwo ati Oloye Ṣẹgun Ọṣọba.

O ni bayii ṣe APC aye igba naa ni tabi PDP Jonathan, o tan imọlẹ si pe ko to di pe wọn pe ni APC, ti wọn n pe ni AD, AC lawọn ti jọ wa nibẹ.

George ṣalaye pe ẹgbẹ oṣelu ọhun ti yipada nnkan to si n ṣèlẹ ni oe lẹyin ti wọn ba dibo tan, wọn yoo wa lọ ko awọn kan wa lati Eko,wọn a ni abẹ wọn lawa taa ṣiṣẹ fun wọn gbọdọ wa.

O waa ni kin ni anfaani pe o ṣiṣẹ fun eeyan asiko to wa yẹ ki o sanjọ fun wọn, o o le ṣe, ki wa ni wahala tawọn yẹn ti ṣe.Irẹjẹ nla ni oun ka sii.

Bẹẹ lo sọ pe ni gbogbo igba naa, oun ko tete fi ẹgbẹ silẹ, amọ oun ko bawọn da si bo ṣe n lọ mọ ni.

Oludije fun ipo sẹnetọ ọhun tun fikun ọrọ ẹ pe bi wọn ba sọrọ nipa Ogun Central, wọn a ni Ọṣọba ni ero tiẹ, Amosun naa lero tiẹ, bẹẹ naa ni wọn yoo tun darukọ temi naa pe mo lero temi.

O ni nnkan to fi jẹ bẹẹ ni pe efin niwa, to ba ti huwa daadaa awọn eeyan a tẹle ẹ ati pe Baba oun sọ nigba to wa laye pe gbogbo nnkan ti mo ba n ṣe ki n ba oun lorukọ jẹ,oun ni oun si tẹle di akoko yii.

O ni ibi toun ko ba ti ni wulo fawọn eeyan,oun maa gbadura pe ki oun ma debẹ.

No comments:

Post a Comment

Pages