Ẹgbẹ CCP fatilẹyin wọn han si George Taylor fun ipo sẹnetọ - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Monday, 19 October 2026

Ẹgbẹ CCP fatilẹyin wọn han si George Taylor fun ipo sẹnetọ

Pẹlu bi eto idibo gbogboogbo ṣe n wọle wẹrẹ bẹẹ lawọn araalu n fi atilẹyin won han si Ọnarebu Geroge Taylor, oludije fun ipo sẹnetọ labẹ ẹgbẹ oṣelu ADC, fun agbegbe Ogun Central.

Irufẹ nnkan bẹẹ lo tun waye lọjọ Aiku,Sannde, nigba ti ẹgbẹ kan ti wọn pe ni CCP, ko ara wọn jọ, ti wọn ni ki oludije naa ma foya, awọn yoo dibo wọn fun un.

Nibi ipade ti wọn ṣe ọhun ni wọn ti Geroge Taylor lọkan balẹ pe awọn yoo fi kaadi idibo wọn gbe e wọle.

Ọkan lara awọn to sọrọ lọjọ naa sọ pe bi wọn ṣe n wo ẹgbẹ wọn, awọn pọ ju bayii lọ,pẹlu ieri pe wọn yoo tan imọlẹ ibo Taylor kaakiri ibi gbogbo.

Ninu ọrọ oludije naa, o dupẹ lọwọ awọn ọmọ ẹgbẹ CCP lori bi wọn ṣe gba oun tọwọ tẹsẹ ati pe ohun kan pataki to wa lọkan oun bi wọn ba fi le dibo yan oun wọle ni lati mu irọrun ba gbogbo awọn to wa ni Ogun Central to fẹẹ lọ ṣoju fun.

No comments:

Post a Comment

Pages